THE MEANING OF YORÙBÁ RONU: ORÍKÌ ‘YORÙBÁ RONÚ’YORÙBÁ RONÚ –

Philips Oluwakemi – 2nd Runner up

Kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì méjì ló ṣe ìgbéró fún àkòrí tí à ń yè̩wò yìí. Àkókó ni Yorùbá tí ìkejì sì jẹ́ Ronú. Ó ye̩ kí á se akitiyan láti ríi dájú pé a tan iná wádìí àwo̩n ò̩rò̩ méjéèjì yìí kí ohun tí a fé̩ yè̩wò gan le yé wa kúnná-kúnná. Àwo̩n àgbà náà ló bò̩ tí wó̩n ní:  “bí igi bá ré lu igi, tòkè rè̩ la kó̩ ń gbé”. 

À̀̀̀̀wọn wo ni à ń pè ní Yorùbá?́ (who are the Yorubas?)

Ní èdè kúkúrú, àwọ̩n Yorùbá ni àwọn tó jé̩ o̩mo̩ Odùduwà pátápátá káríayé, tí ìlú Ilé-Ifè̩ sì jé̩ orírun wo̩n. A tún lè pè wó̩n ní àwo̩n ìpín ènìyàn tó jẹ́ Olùgbé àwọn ìpínlè̩ bíi Ògùn, Òǹdó, Ò̩sun, Ò̩yó̩, Èkìtì, Èkó, Ìlo̩rin àti apá kan ní ìpínlè̩ Kogí àti Edo. Àwọn Yorùbá náà tún wà ní ilè Olómìnira Tógo, Benin, Ghana, Brazil, Cuba àti àwọn orílé̩-èdè mìíràn jákèjádò àgbáyé. Ì̀ran Yorùbá jé̩ ìran tó pò̩, tó lààmìlaaka, tó gbajúmò̩, tó sì gbójúgbóyà. Ìlú kò̩ò̩kan ló ní O̩ba aládé tó ń se àkóso wo̩n ní ilè̩ Yorùbá, Ọmọlúàbí sì ni wọ̩́n pẹ̩̀lú. Oníláàkáyè è̩dá àti aláròjinlè̩ tún ní àwọn Yorùbá. Ò̩pò̩lo̩pò̩ oríire àti ìtè̩siwájú ló̩ló̩kan-ò-jò̩kan ló sì ti dé bá wo̩n ní ibi gbogbo tí wó̩n tè̩dó sí.  

Kí ni ìtumò̩ Ronú?: Ronú jé̩ ò̩rò̩ tí a s̩è̩dá láti inú ò̩̩rò̩ Yorùbá méjì tíí ṣe ‘Èrò’ àti ‘inú’. Èrò túmọ̀ sí ohun tó ń sọ kúlú tàbí jìjàdù lọ́kàn ẹni tí a ó tíì bá ẹlòmíràn sọ tàbí tí a ò tíì fi sí ìs̩e tàbí gbé jáde. Èrò lohun tó ń ṣokùnfà gbogbo ìṣe ènìyàn pátá. Inú sì ni ibùjókòó èrò, ibè̩ ni a ti ń kó̩kó̩ ṣe àgbékalè̩ èrò wa, tí èrò wa bá gún tàbí kò gùn, ó dá lóríi irú àròjinlè̩ tí a bá ní àti irú inú tí olúwarẹ̀ bá ní. 

Láti wá tan ìmó̩lè̩ sí ìtumò̩ ò̩rò̩ yìí dáadáa, yóò jẹ̩́ ohun tó tọ̩̀nà tí ó sì yẹ̩ kí á se àgbéyè̩wò èrò ògbóǹtarìgì akéwì kan, Olóyè Adébáyò Fálétí wò, tó kọ̩ nínú ewì ‘Dídáké Akéwì’ láti ìlà 5 –14

“…sùgbó̩n ta ní mohun táḱéwì ń rò nínú? 

Ta ní le mò̩ràn tí ń bẹ̩ níkùn odò ọ̩̀mò̩ràn? 

Ta ní Morin táko̩rìn fé̩ kò̩ lé̩nu? 

Omi tí kò jàgbè̩ lójú, 

Ó́ lè dénú akéwì kó dòkun, 

Ó le dénú akéwì kó dò̩sà. 

È̩fúùfù tó sì ń mòkun-mòòsa, 

Ó́ le dénú akéwì, 

Kó má jooru ẹnu lọ̩…”

Ewì òkè yìí n sàfihàn lọ́nà tó lè gbà yẹ́ni yékéyéké irú itú tí èrò inú ẹni le pa.  Àti wí pé kò sí e̩ni tó lè mo̩ ohun tí a lè dá lárà àfi ìgbà tí a bá gbé èrò inú wa kalè̩. Àròjinlè̩ ló ń mú àrògún wá, àrògún ló sì ń bí às̩eyo̩rí. E̩ni tí kò bá sì wá ní àròjinlè̩ kò lè ní àtinúdá tí yóò fi se ohun tó lààmìlaaka. Ìdí rè̩ nìyí tó fi ye̩ kí gbogbo o̩mo̩ Yorùbá ó ronú.

Ní ò̩nà mìíràn è̩wè̩, a tún lè so̩ pé; Yorùbá Ronú jé̩ èdè ìpèníjà àti ìtanijí fún gbogbo ọmọ Yorùbá nílé-lóko láti ní àròjinlè̩ àti àrògún. Nítorí náà, a lè sọ pé Yorùbá ronú ni ọ̀rọ̀ tó ń sisé̩ kìlò̩kìlò̩ fún àwọn ọmọ Odùduwà pátápátá láti kíyèsára, kí wọ́n sì má sun àsùnpiyè nítorí páńsá tí kò fura á já síná, àjà tí kò fura á jì̀n, onílé tí kò sì fura olè ní kó irú wo̩n lé̩rù lo̩. Irú ìrònú tí à ń mé̩nu bà yìí kìí se ìrònú eréfèé tí kò dó̩kàn lásán, bẹ́ẹ̀ kìí se ìrònú tí kò mú èso rere kan bí tí wù kó mo̩ jáde. Ìrònú tí à ń sọ ní pé ‘kí á pe àró àti odofin inú wa tí wọ̩́n jẹ̩́ olóyè àgbà pàtàkì ní́kùn ọ̩̀mò̩ràn láti ṣe ìpàdé tó ló̩ò̩rìn tí ayé yóò fi gbe̩de̩muke̩ fún te̩rúto̩mo̩ nínú ìran Yorùbá níbikíbi lórílé̩-èdè àgbáyé.

  • THE HISTORY OF “YORÙBÁ RONÚ” (ÌTÀN BÍ YORÙBÁ RONÚ SE BÈ̩RÈ̩)

Kò sí bí a ó se pe orí ajá tí a kò ní porí ìkòkò tí a fi sè é. Bé̩è̩ gan ní ò̩rò̩ orin Yorùbá Ronú àti Hubert Ogunde se rí. Ògbóǹtarìgì akéwì, olórin àti òsèré orí ìtàgé ni Hubert Ogunde nígbà ayé rè̩. A sì bíi ní o̩dún 1916 ní ìlú Ososa, nítòsí Ìjè̩bú-Òde. Hubert Ògunde ló ko̩ eré oníjó-lórin Yorùbá Ronú tó wá di ohun tí gbogbo ayé ń gbà bí e̩ni gba igbá o̩tí. Òtító ni pé nígbà náà gan, àwo̩n ò̩rò̩ inú orin yìi kò fi taratara yé ò̩pò̩ ènìyàn tàbí ní ìtumò̩ sí wo̩n. Sùgbó̩n, àso̩té̩lè̩ ńlá gan-an ni orin yìí jé̩ fún gbogbo o̩mo̩ káàárò̩, o ò jíire.

Yorùbá Ronú ló fé̩rè̩ jé̩ orin tó gbajúmò̩ jù nínú àwo̩n orin tí Ògúǹdé ko̩. Ó sì kó̩kó̩ se eré yìí ní orí ìtàgé ní o̩dún 1964. Orin yìí ló fi se pàsán ìbáwí àti ìpèníjà fún àwo̩n olósèlú E̩kùn Ìwò̩ Oòrùn tí í se ilè̩ Yorùbá nígbà náà. Orin yìí tàbùkù ìgbésè tí àwo̩n olósèlú ilè̩ Yorùbá kan ń gbé láti lè̩dí àpò pò̩ pè̩lú àwo̩n olósèlú ilè̩ ibòmíràn. Látàrí èyí, Ìjo̩ba tó wà lóde nígbà náà fi òfin de e̩gbé̩ eléré orí ìtàgé Hubert Ogunde (the Ogunde theatre) láti gbé orin náà jáde tàbí s̩e é níbikíbi ní orílè̩ èdè Nàíjíríà. Sùgbó̩n ní o̩dún 1966 ni ìjo̩ba ológun gbé ìfòfndè yìí kúrò lórí orin náà.

Àwọn bàbá wá náà lọ́ tún sò̩rò̩ tí wọ̩́n pòwe, wọ̩́n ní “òkùn kìí gùn gùn gùn, kò má ní ibi tó ti gùn wá” àti pé “è̩sé̩ kan kìí dédé ṣé̩”. Òsèré orí́ ìtàgé àti oníjó alárìnká tó gbajúgbajà yìí gbé eré Yorùbá Ronú jáde láti fi ojú laifi wo gbọnmi sii, omi ó  tó ò tó ń ṣele nínú ètò iselu ilé Yoruba. Sugbon, ohun tó yẹ kí a mo gan ni pé, saaju àkókò yìí ni ailasoye, àti àìgbọrà ẹni yẹ tí ń ṣẹlẹ̀ laarin awọn ọmọ Yorùbá. Ìjà ogún kírìjí wá nibe to waye laarin awọn ọmọ ogún Ekiti parapò àti Ọmọ ogún Ibadan, eleyameya, ati ideyesi si n sele kaakiri ninu eto iselu Yoruba, eleyii ko si fun wa ni anfani laati je ki a ri owo mu ninu eto iselu Naijiria. Gbogbo iwonyi ni Ogunde ro to fi gbe orin yii jade. 

Ní ọdún 1964 ni Oloye Hubert Ogunde se agbekale ere ori itage yii, itan ko si ni gbagbe oloogbe naa laelae.

  • THE IMPLICATION OF “YORÙBÁ RONÚ” AND LACK OF: (ÀBÁYO̩RÍSÍ YORÙBÁ RONÚ ÀTI ÀÌSÍ RÈ̩)

Kò sí àwáwí kan níbè̩, láì jé̩ pé àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá bá Ronú, láti jìjàgbara kúrò lóko e̩rú orílè̩-èdè Nàìjíríà tí àwo̩n òyìbó amúnisìn fi wá sí yóò sòro. Àìfèteméte àìfèròmerò ló mú kí o̩mo̩ ìyá méfà kú sí oko ìwò̩fà. Púpò̩ nínú àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá gan ni ojú wo̩n kò tí ì là tàbí kí á so̩ pé o̩kàn wo̩n sì wà nínú ìdè. Àwo̩n mìíràn kò tilè̩ mo̩ odó tí wo̩n yóò da ò̩rúnlá sí. Àwo̩n mìíràn è̩wè̩, ohun tí wo̩n yóò je̩ kò jé̩ kí wó̩n gbó̩n. Yorùbá ronú ni yóò la tolórí-te̩lé̩mù wa lóye, tí a ó sì wà ní ìfo̩wó̩sowó̩pò̩ dípò kí á máa figagbága. 

Yorùbá Ronú yóò jé̩ kí àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá ó mò̩ pé ní àwùjo̩ yòówù tí wó̩n bá wà ìdàgbàsókè Yorùbá ló ye̩ kí ó je̩ wó̩n lógún. Ní ilé is̩é̩ ìjo̩ba, o̩mo̩ Yorùbá yóò le se ìrànló̩wó̩ fún ara wo̩n. Ní pápákò̩ òfurufú, ní ilé ìwé, ní ilé ìfowópamó̩, ní ilé isé̩ àwo̩n o̩mo̩ ológun, ní ibùdókò̩, ní ibikíbi. 

Yorùbá Ronú, yóò jé̩ kí àwo̩n Yorùbá ó máa fé̩ ara wo̩n dípò fífé̩ ará ìta. Yorùbá Ronú yóò jé̩ kí o̩mo̩ Yorùbá ó mò̩ wí pé àkóbá ńlá ni àwo̩n è̩sìn àtò̩húnrìnwá ń se fún ìran wa, dípò bé̩è̩, a ó ò gbájúmó̩ è̩sìn àti às̩à ìb́il̩̀e wa. Bákan náà, yóò mú kí á gbójúgbóyà láti máa fi èdè Yorùbá bá ara wa sò̩rò̩ gé̩gé̩ bíi o̩mo̩ Yorùbá níbikíbi tí a ó sì tún máa fi kó̩ àwo̩n o̩mo̩ wa. Orúko̩ Yorùbá ni a ó máa jé̩ dípò orúko̩ tí a kò mo̩ ìtumò̩ rè̩. Àwo̩n o̩mo̩ yóò mo̩ agboolé baba tó bí wo̩n ló̩mo̩ àti orúko̩ agboolé wo̩n. Yorùbá ronú yóò tún se ìgbéláruge̩ fún ètò o̩rò̩ ajé tó gbòòrò láàrin gbogbo àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá pátá. 

  • APPLICATION OF YORÙBÁ RONÚ (SÍS̩E ÀMÚLÒ YORÙBÁ RONÚ)

Yoruba Ronú kì í se ò̩rò̩ tó ye̩ kí á fi mo̩ lórí ò̩rò̩ òsèlú nìkan. Fìló̩só̩fì tó lágbára gan ni tí a kò sì gbo̩dò̩ fi o̩wo̩ ye̩pe̩re̩ mú u. A gbó̩dò̩ lo agbára tó wà nínú ò̩rò̩ yìí láti kojú gbogbo ìpèníjà tó lè máa dojú ko̩ ìdàgbàsókè àti ìgbéga orílè̩-èdè Yorùbá pátá.Òpó mé̩rin pàtàkì ló gbé ilé ayé ró tó sì se kókó sí ìgbé ayé àti àseyo̩rí àwùjo̩ kò̩ò̩kan káàkiri àgbáyé. Yorùbá Ronú yóò s̩e àtúnse àti àmójútó tó ló̩ò̩rìn ní àwo̩n òpó mé̩rè̩rin wò̩nyí tí a bá se àmúlò àti àgbékalè̩ rè̩ dáadáa. Àwo̩n òpó náà ni: 

  1. Òpó Òsèlú (Politics): ṣíṣe àmúlò Yorùbá ronú yóò jẹ́ kí gbogbo ọmọ Odùduwà ṣe ara wọn ní òṣùṣù ọwọ̀ kí á sì jọ sọ àsọyépọ̀ lórí ọ̀nà tí a ó gbà láti ríi dájú pé ọmọ Yorùbá ló wà ní àwọn ipò tó ṣe pàtàkì ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní ibikíbi tí àwọn ọmọYorùbá bá wà ní àgbáyé. Ohun tó wá jé̩ pabanbarì rè̩ tó sì se pàtàkì ni pé, Yorùbá Ronú yóò jé̩ kí gbogbo àwo̩n olósèlú o̩mo̩ Yorùbá ó lo agbára àti ipò tí wó̩n wà láti fi ja ìjà òmìnira fún orílè-èdè Yorùbá láti dádúró gé̩gé̩ bí i orílè-èdè olómìnira. Nítorí, kò sí eré tí ajá fé̩ má a bá e̩kùn se. Kí o̩ló̩mú̩ dá o̩mú̩ ìyá̩ rè̩ gbé. Ibi tí a bá ti pè ní orí, kò tún ye̩ kí á tún fi ibè̩ te̩lè̩ ni àwo̩n Yorùbá máa ń wí, sùgbó̩n, ó seni láàánú láti mò̩ wí pé Yorùbá jé̩ orí sùgbó̩n, a kò sàkíyèsí ipò àgbà tí Olódùmarè gbé wa sí. Tí a bá ronú jinlè̩, tí a pe àró àti ò̩dò̩fin inú wa gúnlè̩, tí a sì gbìmò̩ràn pò̩ olósèlú o̩mo̩ Yorùbá kan kò ní máa rí olósèlú o̩mo̩ Yorùbá mìíràn gé̩gé̩ bí ò̩tá̩ rè̩ sùgbó̩n gé̩gé̩ bí alábàásisé̩ pò̩ sí irere àti ìlo̩síwájú ilè̩ Yorùbá. Ohun mìíràn tún ni pé “Yorùbá Ronú” yóò mú wa ro àròjinlè̩ lórí i o̩gbó̩n tí a ó dá gé̩gé̩ bí i ìran kan láti mo̩ ohun tí a ó mú se láti gba òmìnira kí á sì dádúró gé̩gé bíi Orílè̩-èdè. Yoruba Ronu yóò jé̩ kí àwo̩n aláìmò̩kan nínú àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá tó ń lè̩dí̩ àpò pò̩ pè̩lú̩ àwo̩n ò̩tá ó mò̩ pé “ile ni a ti ń kó è̩s̩ó̩ ròde” àti wí pé, bí ará ilé e̩ni ò dára, bí ènìyàn e̩ni kò sunwò̩n, a kò ní fi wé aláàárò lásán. Ìrònú arojinle ni yóò jé̩ kó yé wa yéké pé e̩ni tó bá ni èkù ló ni ò̩be̩ ni ò̩rò̩ òsèlú Nàìjíríà ní àkókò yìí. 
  1. Òpó O̩rò̩-ajé (Economy): nínú ò̩rò̩ ètò o̩rò̩-ajè Orílè-èdè Nàìjíríà, kò sí àwáwí kankan níbè̩, ohun tó dájú ni pé Yorùbá ni ó mókè sùgbó̩n nítorí pé à ń fi o̩wó̩ ara wa gbé oúnje̩ alé̩ wa fún ológbò je̩ kò jé̩ kí ìtè̩siwájú tó ti ju èyí lo̩ ti dé bá ìran wa. Yorùbá Ronú yóo jé̩ kí á mò̩ pé̩ àsìkò tí tó tí oníkálùkù yóò máa se o̩de̩ rè̩ ló̩tò̩ò̩tò̩. Torí pé kò sí èrè olóókan nínú àpapín síse. Nígbà ayé àwo̩n baba ńlá wa, owó kòkó àti àwo̩n ohun ò̩gbìn mìíràn tó fún wa ní níná. Nísisìyí pè̩lú, àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá kìí se ò̩le̩ .Yorùbá ló ni Òkun tó ń pa owó ribiribi wo̩lé ní ìlú Èkó, epo rò̩bì tún wà ní Ìpínlè̩ Òǹdó àti àwo̩n òhun àlùmò̩ó̩nì mìíràn tó ń pa owó wo̩lé fún àwo̩n tí kìí se o̩mo̩ Yorùbá. 

Púpò̩ nínú àwo̩n ènìyàn tó di ipò pàtàki mú lá̩gbo̩n ètò ìsúná jé̩ o̩mo̩ bíbí ilè̩ Yorùbá. Àwo̩n ògúnná gbòǹgbò tó di ipò às̩e̩ mú ní è̩ka ètò ìsúná ní orílè̩ èdè yìí ló sì jé̩ o̩mo̩ Yorùbá. Àwo̩n bíi Fé̩mi Ò̩té̩do̩lá, Mike Adénúgà, Fó̩ló̩runs̩ó̩ Alákijà àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩. Lágbo̩n àwo̩n òsèré àti olórin bákan náà, àwo̩n tó je̩ o̩mo̩ Yorùbá ló ń lékè ní ilè̩ yìí àti lókè òkun. Àwo̩n òs̩èré o̩mo̩ Yorùbá ló gbajúgbajà jùlo̩ ní gbogbo ilè̩ Áfíríkà. Àwo̩n bíi: Fúnké̩ Akíndélé, Fé̩mi Adébáyò̩, Níyì Akínmó̩láyan, David Adélékè (Davido), Ayo̩bámi Balógun (Wizkid), Hammed O̩ló̩ládé (Às̩àké̩), Olamide, Tiwa Savage, Simí àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩. Tó túmò̩ sí pé Yorùbá ló ń pa owó wo̩lé jù ní agbo̩n yìí àti àwo̩n agbo̩n mìíràn.

Gbogbo àwo̩n ibùdó pàtàkì tí a ti ń kó o̩jà wo̩lé láti òkè òkun àti àwo̩n ilè ibòmíràn ló jé̩ Yorùbá. Yorùbá ronú yóò jé̩ kí á mò̩ wí pé àsìkò ti tó tí o̩ló̩mú yóò dá o̩mú ìyá rè̩ gbé. Kò ye̩ kí sis̩é̩-sis̩é̩ ó wà lóòrùn kí náwónáwó ó wà ní ibòòji. 

  1. Òpó È̩sìn àti Às̩à (Religion and culture): è̩sìn ìbílè̩ Yorùbá ni è̩sìn àbáláyé tí ò̩pò̩lo̩pò̩ è̩kó̩, o̩gbó̩n, ìmò̩ àti òye tí a kò lè kó tán sì sodo sí inú rè̩. S̩ùgbó̩n ó jé̩ ohun tó seni láàánú láti mò̩ wí pé o̩wó̩ òsi ni púpò̩ nínú àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá fi ńjúweilé baba wo̩n. Dípò àwo̩n èsìn àbáláyé Yorùbá àwo̩n è̩sìn àtò̩húnrìnwá tí kò bá ojú àmúwayé wa mu là ń gbé larúge̩. Àwo̩n àgbà náà ló pòwe pé “o̩mo̩ tó bá so̩ iĺe nù, ó so àpò ìyà kó̩”. Yorùbá Ronú ni yóò jé̩ kí á mò̩ pé nǹkan ki sínú às̩à Yorùbá. Às̩à oge sís̩e, as̩o̩ wíwò̩, ìkíni, ìranra-e̩ni ló̩wó̩, ìwà o̩mo̩lúàbí àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩ tó jé̩ pé ò̩pò̩lo̩pò̩ è̩kó̩ la lè rí kó̩ nínú wo̩n. Kí è̩sìn àtò̩húnrìnwá tó dé ni a ti mò̩ wí pé kò ye̩ kí á jalè gé̩gé̩ bí o̩mo̩ Yorùbá. Ohun tó jé̩ tiwa kò wù wá, ohun olóhun ni ó ń yá wa lára. 

Kí o̩kùnrin dò̩bálè̩ kí àwo̩n òbí àti àwo̩n àgbàlagbà ti ròkun ìgbàgbé, orúnkún méjéèjì o̩mo̩obìnrin kò le kanlè̩ láti kí àgbà mó̩. Ayé wá di rúdurùdu nítorí pé a so̩ àwo̩n ohun àmúsagbára wa nù. Àwo̩n ò̩dó̩mo̩kùnrin àti ò̩dó̩mo̩bìnrin tó ye̩ kó tún máa lo àwo̩n agbára wò̩nyí ló̩nà tó dára ló ń se àsejù nítorí pé kò sí àwo̩n àgbà tí yóò tó̩ wo̩n só̩nà. È̩sìn ìgbàgbó̩ kó̩ ló kó̩ wa pé kí á má jalè, è̩sìn Ìmàle kó̩ ló sì ní ká má pànìyàn, gbogbo ìwò̩nyí ló wà nínú è̩sìn àti àsà ìbílè̩ Yorùbá kí àwo̩n è̩sìn àtò̩húnrìnwá tó dé. 

As̩o̩ tó wuyì tó sì re̩wà ni Yorùbá ń wò̩ tí wó̩n fi ń bo àsírí ara. Àwo̩n as̩o̩ Òfì àti Àdìre̩ lo ́di ohun tí a patì nítorí ò̩làjú àlàsódì. Ó mà se ò! O̩ko̩ àti ìyàwó á tún gbé ara wo̩n lo̩ sí kóòtù tàbí só̩ò̩sì lé̩yìn tí wó̩n ti se ìgbéyàwó ìbílè̩ tán. Ta ló ha fi irú èyí kàn wá? Kò sí síse kò sí àìse, Yorùbá Ronú ni yóò là wá ló̩yè̩. Yorùbá Ronú ni yóò lalè̩ wù bí ò̩wàrà òjò tí yóò sì sí te̩rúto̩mo̩ níyè kúrò nínú èèdì ojó̩ tó ti pé̩.

Se bí wó̩n ní orúko̩ o̩mo̩ ni ìjánu o̩mo̩, sùgbó̩n ò̩rò̩ ti di bámìíràn báyìí nítorí pé orúko̩ tí a kò mo̩ ìtumò̩ rè̩ là ń so̩ àwo̩n o̩mo̩ wa. Bé̩è̩ sì rèé, àwo̩n orúko̩ tó yááyì, tó ní ìtumò̩ tó sì ń mó̩ni lára ni àwo̩n orúko̩ Yorùbá̩. Àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá ti di o̩mo̩ o̩ló̩mo̩ ní ilè̩ òkèrè nítorí pé, bàbá àti ìyá kò̩ láti mú àwo̩n o̩mo̩ lo̩ sí ìlú àti agbo ilé tí wó̩n ti bí wo̩n. Yorùbá Ronú ni yóò jé̩ kí gbogbo ìwò̩nyí ó di ohun àtijó̩ nígbà tí a bá ti yo̩ àwo̩n kànǹda inú ìre̩sì kúrò tán.

  1. Òpó ìbágbépò̩ o̩mo̩ è̩dá (Social and relationship): nǹkan ni e̩ye̩ ń je̩ ḱi àgbàdó tó dáyé. Yorùbá Ronú yóò so̩ wá jí, tí a ó sì ní àròjinlè̩ pé Yorùbá ní ìlànà ètò è̩kó̩ tó jíire tó sì se ìté̩wó̩gbà káàkiri àgbáyé lórí i bí a se ń bá ara wag bé pò̩ ní àlàáfíà. Àló̩ pípa, è̩kó̩ ilé, àwo̩n ewì aje̩mé̩sìn àti aje̩má̩ye̩ye̩ ló̩ló̩kan ò jò̩kan ni àwo̩n Yorùbá fi máa ń kó ara wo̩n jo̩ láti se àseye̩ tàbí o̩dún ìbílè̩. Ohun tó seni láàánú ni pé ò̩pò̩ o̩mo̩ Yorùbá ni kò rí ohun tó daŕa nínú kí wó̩n fi o̩mo̩bìnrin Yorùbá se aya. Bé̩è̩ sì ni ojúkòkòrò àti olè kò lè jé̩ kí o̩mo̩bìnrin Yorùbá ó rí o̩mo̩kùnrin Yorùbá gé̩gé̩ bí e̩ni tí òun le fi se adé orí àfi àwo̩n òyìnbó aláwò̩ funfun àti àwo̩n è̩yà mìíràn. Wo̩n kò mò̩ pé ohun tí yóò tán ni o̩dún Eégún, tí o̩mo̩ alágbaà á padà fi àkàrà je̩ è̩ko̩. Àti pé ìgbè̩yìn n ií dun olókùú àdá.
  • ELEVATION OF YORUBA RONU PHILOSOPHY (ÌGBÉLÁRUGE̩ OJÚ FILOSOFI/ÀMÚWAYÉ YORÙBÁ RONÚ)

Àwo̩n ò̩nà tí a lè gbà se ìgbéláruge̩ fìló̩ś̩ofì Yorùbá Ronú kò lóǹkà, sùgbó̩n díè̩ nínú wo̩n ni ìwò̩nyí:

  1. Ìdánilé̩kò̩ó̩ Orí Rédíò àti Te̩lifísàn: púpò̩ nínú àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá tí kò mò̩ó̩ko̩ tàbí mò̩ó̩kà ni ó máa ń wo móhùnmáwòrán àti rédíò. Ìdánilé̩kò̩ó̩ yìí yóò ta wó̩n lólobó láti mo̩ ohun tó ń se̩lè̩ àti ohun tí wó̩n lè se láti gbé orílè̩-èdè Yorùbá láruge̩. Púpò̩ àwo̩n àgbàlagbà ni wó̩n ní o̩gbó̩n nínú sùgbó̩n tí wo̩n kò mo̩ ò̩na tí wó̩n lè tò̩ tí wo̩n yóò fi se ìrànló̩wó̩ tó ye̩ fún orílè̩ èdè Yorùbá.
  2. Ìdánilé̩kò̩ó̩ lórí àwo̩n ìkànnì àti òpó ìbára-e̩ni-sò̩rò̩ Ayélujára: orí àwo̩n òpo ìbára-e̩ni-sò̩rò̩ ayélujára ni ò̩pò̩lo̩pò̩ àwo̩n ò̩dó̩ tí kò mo̩ nǹkankan wà s̩ùgbó̩n tí wó̩n lè wúlò fún ìtè̩síwájú Fìló̩só̩fì Yorùbá Ronú. Ìdánilé̩kò̩ó̩ orí è̩ro̩ ayélujára yìí le má so èso rere ní kíákíá sùgbó̩n bí a bá te̩pe̩le̩ mó̩ o̩, tí a sì ń gbìyànjú láti lo ìlànà ìfikùnlukùn àti ìlaniló̩yè̩, ó seése kí ò̩pò̩ àwo̩n ò̩dó̩ wò̩nyí yí o̩kàn wo̩n padà kí wón sì ní ìgbàgbó̩ nínú ohun tí á ń se. Síse àgbékalè̩ fìló̩só̩fì Yorùbá Ronú nílò ò̩pò̩lo̩pò̩ àwo̩n ò̩dó̩ tí yóò le máa tan FÌLÓ̩SÓ̩FÌ yìí káàkiri.
  3. Síse àgbékalè̩ àwo̩n ìpàdé àpérò ní ìpínlè̩ kò̩ò̩kan àti ni e̩lé̩kùnje̩kùn: ìpàdé àpérò lóòrèkóòrè ní àwo̩n ìpínlè̩, e̩kùn àti orílè̩-èdè tí àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá wà káàkiri àgbáyé. Àpérò yìí kò yo̩ àwo̩n ilé isé̩ ìjo̩ba àti àdáni náà sílè̩ nítorí pé yóò se ìrànwó̩ pàtàkì fún ìpolongo Fìló̩só̩fì Yorùbá Ronú. Tí a bá ti ibi pe̩le̩be̩ mú ò̩lè̩lè̩ je̩, láìpé̩ láìjìnà ni àwo̩n ìpàdé àpérò wò̩nyí yóò di ohun tí gbogbo ayé fo̩wó̩ sí.
  4. Ìdásílè̩ àti ìpèsè ìrànwó̩ fún àwo̩n e̩gbé̩ asègbè fún àwo̩n Yorùbá bíi (THINK YORUBA FIRST): ò̩pò̩lo̩pò̩ àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá ló ti rí tajé se tí Elédùmarè sì ti ké̩ wo̩n sùgbó̩n tí wo̩n kò mo̩ ò̩nà tó dára láti ná owó wo̩n tàbí ibi tí wo̩n yóò ná owó wo̩n sí gan. A lè ko̩ ìwé sí irú àwo̩n ènìyàn wò̩nyí láti se àtìle̩yìn fún ìgbéláruge̩ Fìló̩só̩fì Yorùbá Ronú.

ÌKÁDÌÍ: ní ìparí, Yoruba Ronú kì í se ò̩rò̩ tó ye̩ kí á fi mo̩ lórí ò̩rò̩ òsèlú nìkan. Fìló̩só̩fì tó lágbára gan ni tí a kò sì gbo̩dò̩ fi o̩wo̩ ye̩pe̩re̩ mú u. A gbó̩dò̩ lo agbára tó wà nínú ò̩rò̩ yìí láti kojú gbogbo ìpèníjà tó lè máa dojú ko̩ ìdàgbàsókè àti ìgbéga orílè̩-èdè Yorùbá pátá. Ìfo̩wó̩sowó̩pò̩ gbogbo o̩mo̩ Yorùbá pátá ló lè se àtìle̩yìn fún Fìló̩só̩fì̩ Yorùbá Ronú láti se àseyorí tó ló̩ò̩rìn kí ó sì fi ìdí mú̩lè̩. Ìrònú ló ń se ató̩kùn fún àseyó̩ri tó ló̩ò̩rìn láyé, nítorí náà ni gbogbo o̩mo̩ Yorùbá gbó̩dò̩ fi ní àròjinlè tí yóò là wá nínú ìdojúko̩ tó ń bá wa fínra gé̩gé̩ bí ìran ènìyàn. Ire o.

Philips Olúwaké̩mi, 

Àkúré̩, Orílè̩-èdè Yorùbá.

Osù Ògún, O2023.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *